- mp Ọlọrun, Baba mi, ‘Wọ npè
Aṣako ọmọ Rẹ mọra?
cr Iwọ o ha dariji mi?
p Mo de, mo de, jọ gbà mi la.
- mp A! Jesu, Iwọ nrekọja
Pẹlu ore at’ agbara?
cr ‘Wọ kò ha ngbọ́ igbe mi bi?
p Mo de, mo de, ṣanu fun mi.
- mp A! Ẹmi Mimọ, Iwọ ni?
Ọrẹ ti mo ti ṣati pẹ!
‘Wọ ha mbẹ̀bẹ fun mi sibẹ?
p Mo de, mo de, m’ailera le.
- cr Mo de, Oluwa, ifẹ Rẹ
Ni o nrọ̀ mi t’o sì nfà mi:
f Mo wolọ̀ lẹsẹ Rẹ, ki mmọ̀
B’o ti dùn lati jẹ Tire. Amin.