Hymn 187: There were ninety and nine that safely lay

Mokandilogorun dubule je

  1. mf Mọkandilọgọrun dubulẹ jẹ
    Labẹ oji nin’ agbo;
    di Ṣugbọn ọkan jẹ lọ or’oke,
    Jina s’ ilẹkun wura:
    p Jina réré lor’ oke ṣiṣa,
    Jina rere s’ Oluṣagutan.

  2. cr “Mọkandilọgọrun Tirẹ l’ eyi :
    Jesu, nwọn kò ha to fun Ọ?”
    p Oluṣagutan dahùn, “Temi yi
    Ti ṣako lọ lọdọ mi;
    mf B’ ọ̀na tilẹ ti palapala,
    Ngo w’ aginju lọ w’ agutan mi.”

  3. mp Ọkan nin’ awọn t’a rà pada,
    Kò mọ̀ jijin omi na;
    cr Ati dudu oru ti Jesu kọja,
    K’ o to r’ agutan Rẹ̀ he;
    L’ aginju réré l’o gbọ ‘gbe rẹ̀,---
    pp O ti rẹ tan, o si ti ku tan.

  4. mf “Nibo ni ẹjẹ ni ti nkán wá,
    T’ o fi’ọ̀na or’òke hàn?”
    “A ta silẹ f’ẹnikan t’o ṣako,
    K’Oluṣagutan to mu pada.”
    “Jesu kil’ o gún ọwọ Rẹ bẹ?”
    “Ẹgun pupọ l’o gun mi nibẹ.”

  5. f Ṣugbọn ni gbogbo ori òke
    Ati lori apata,
    Igbe ta d’òke ọrun wipe,
    “Yọ̀ mo r’agutan mi he.”
    ff Yitẹ ka l’ awọn angẹl ngba,
    Yọ̀, Jesu m’ohun Tirẹ pada.” Amin.