- f Ji ‘ṣẹ Rẹ nde, Jesu!
Fi agbara Rẹ hàn !
ff Fọhùn t’o le j’oku dide !
Mu k’enia Rẹ gbọ.
- f Ji ‘ṣẹ Rẹ nde, Jesu!
Tọ́ orun iku yi !
Fi Ẹmi agbara nla Rẹ
Ji ọkàn ti ntogbe.
- mf Ji ‘ṣẹ Rẹ nde, Jesu!
di Mu k’ ongbẹ Rẹ gbẹ wa:
p Sì mu k’ebi pa ọkàn wa,
Fun onje iye na.
- cr Ji ‘ṣẹ Rẹ nde, Jesu!
Gbe orukọ Rẹ ga:
Mu k’ ifẹ Rẹ kùn ọkàn wa,
Nipa Ẹmi Mimọ.
- cr Ji ‘ṣẹ Rẹ nde, Jesu!
Rọjo itura Rẹ;
ff Ogo y’o jẹ Tire nikan,
K’ ibukun jẹ tiwa. Amin.