- mf Jesu, l’ara Rẹ l’ awa nwò
Ẹgbẹgbẹrun ogo:
Ju t’ okuta iyebiye,
T’ agbada Aaroni.
- Nwọn kò le ṣai kọ rubọ na,
p Fun ẹṣẹ ara wọn:
Iwa Rẹ pe, kò l’abawọn,
Mimọ si l’Ẹda Rẹ.
- Jesu Ọba ogo gunwà
L’Oke Sion t’ ọrun:
p Bi Ọdọ-agutan t’a pa,
Bi Alufa nla wa.
- f Alagbawi lọdọ Baba,
Ti y’o wà titi lai;
Gb’ ẹjọ rẹ fun, ‘wọ ọkàn mi,
Gb’ ore-ọfẹ Baba. Amin.