- mf Gbogbo ẹjẹ ẹran,
Ti pẹpẹ awọn Ju;
Kò lè f’ ọkàn l’ alafia,
Kò lè wẹ eri nù.
- Kristi Ọd’agutan,
p M’ẹ̀ṣẹ wa gbogbo lọ;
Ẹbọ t’ o ni orukọ nla,
T’ o ju ẹjẹ wọn lo.
- mf Mo f’ igbagbọ gb’ ọwọ
Le ori Rẹ ọwọ́n;
B’ ẹnt’ o ronupiwada,
Mo jẹ́wọ ẹ̀ṣẹ mi.
- Ọkàn mi npadà wò
p Ẹrù t’ Iwọ ti rù;
Nigbati a kàn Ọ mọ ‘gi,
Ẹṣẹ rẹ̀ wa nibẹ.
- f Awa nyọ̀ ni ‘gbagbọ,
Bi egún ti kurò,
ff Awa nyin Ọdọ-agutan,
A nkọrin ifẹ rè. Amin.