- mp Arẹ̀ mu ọ, aiye sú ọ,
Lala pọ̀ fun ọ?
mf Jesu ni, “Wá si ọdọ mi,
p K’ o simi.”
- mf Ami wo l’ emi o fi mọ̀,
Pe On l’ o npè mi?
p Am’ iṣó wà lọwọ, ati
Ẹsẹ Rẹ̀.
- mf O ha ni ade bi ỌBa,
Ti mo lè fi mọ?
cr Totọ, ade wà lori Rẹ̀,
p T’ ẹgun ni.
- mf Bi mo ba ri, bi mo tẹle;
Kini ère mi?
p Ọpọlọpọ iya ati
‘Banuje.
- mf Bi mo tẹ̀le tit’ aiye mi,
Kini ngo ri gba?
f Ẹkun a dopin, o simi,
cr Tit’ aiye.
- mf Bi mo bère pe, k’ O gbà mi,
Y’o kọ̀ fun mi bi?
f B’ ọrun at’ aiye nkọja lọ,
p Kò jẹ kọ̀.
- cr Bi mo ba ri, ti mo ntẹ̀le,
Y’o ha bukun mi?
ff Awọn ogun ọrun nwipe,
Yio ṣe. Amin.