- mf Ọlọrun ‘yanu! ọ̀na kan
Ti o dabi Tirẹ kò si:
Gbogb’ ogo ore-ọfẹ Rẹ,
L’ o farahàn bi Ọlọrun.
ff Tal’ Ọlọrun ti ndariji,
Ore tal’ o pọ̀ bi Tirẹ?
- mf N’ iyanu at’ ayọ̀ l’ a gbà
Idariji Ọlọrun wa;
p ‘Dariji f’ ẹ̀ṣẹ t’ o tobi,
T’ a f’ ẹjẹ Jesu ṣ’ edidi.
ff Tal’ Ọlọrun, &c.
- Jẹ ki ore-ọfẹ Rẹ yi,
Ifẹ iyanu nla Rẹ yi,
K’ o f’ iyin kun gbogbo aiye,
Pẹlu ẹgbẹ Angẹl l’ oke.
ff Tal’ Ọlọrun, &c. Amin.