- f Mo f’ igbagbọ b’Ọlọrun rìn,
Ọrun ni opin ajo mi,
“Ọp’ at’ ọgọ Rẹ́ tu mi n’nu,”
Ọna didun l’ ọna t’ o là.
- f Mo nrin l’arin aginju nla,
p Nibi ọpọlọpọ ti nù;
Ṣugbọn on t’ o ṣamona wa,
Kò jẹ ki nṣina, ti mba nù.
- Mo nla ‘kẹkùn t’ on ewi ja.
Aiye at’ Eṣu kọlu mi;
Agbara Rẹ̀ ni mo fi la,
Igbagbọ si ni ‘ṣẹgun mi.
- p Mo nkanu awọn ti nhalẹ,
F’afẹ aiye ti nkọja yi;
f Oluwa jẹ ki mba Ọ rin,
Olugbala at’ Ọrẹ mi. Amin.