- mp Baba, a tun pade l’okọ Jesu,
A si wa tẹriba lab’ ẹsẹ Rẹ:
A tun fe gb’ohun wa sòké si Ọ
Lati wá anu, lati kọorin ‘yin.
- f A yin Ọ fun itọju ‘gbagbogbo,
Ojojumo l’ ao ma rohin ‘ṣẹ rẹ:
Wiwa laye wa, anu Rẹ ha kọ?
Apa Rẹ ki o fi ngba ni mọra?
- p O ṣe! a ko yẹ fun ifẹ nla Re,
A ṣako kuro lọdọ Rẹ pọju;
mf Ṣugbọn kikankikan ni O si npe;
Njẹ, a de, a pada wa ‘le, Baba.
- mp Nipa okọ t’o bor’ ohun gbogbo,
Nipa ifẹ t’o ta ‘fẹ gbogbo yọ,
Nipa ẹjẹ ti a ta fun ẹṣẹ.
cr Ṣilẹkun anu, sì gbani si ‘le. Amin.