- mf F’ ore-ọfẹ Rẹ ba wa gbe,
Jesu Olugbala;
Ki ẹni arekereke,
K’o má le kọlu wa.
- mf F’ ọrọ mimọ́ Rẹ ba wa gbe,
Jesu iyebiye;
K’ a ri igbala on iyè,
Lọhun, bi nihinyi.
- Fi ‘bukun Tirẹ ba wa gbe,
Oluwa Ọlọrọ̀;
Fi ẹbùn ọrun rere Rẹ,
Fun wa l’ọpọlọpọ.
- f Fi ‘pamọ Tirẹ ba wa gbe,
ff Iwọ Alagbara;
K’awa k’ o lè ṣa ọta tì,
K’aiye k’ o má dè wa.
- Fi otito Rẹ ba wa gbe,
Ọlọrun Olore:
Ninu ‘pọnju, wá ba wa rẹ́,
Mu wa fi ori ti.
- f F’ alafia Rẹ ba wa gbe,
p Nigbat’ iku ba de;
N’iṣẹju na, sọ fun wa, pe,
ff Igbala nyin ti de. Amin.