- mf Jesu, emi o fi ọkàn mi fun Ọ;
mp Mo jẹbi, mo gbé, ṣugbọn ‘Wọ le gbà mi.
cr L’aiye ati l’ọrun, kò s’ẹni bi Rẹ:
p Iwọ ku f’ẹlẹṣẹ, --- f’emi na pẹlu.
- mf Jesu, mo le simi le orukọ Rẹ,
Ti angẹli wa sọ, l’ọjọ ibi Rẹ;
p ‘Yi t’a kọ, ti o hàn l’or’ agbelebu,
cr Ti ẹlẹṣẹ si kà; nwọn si tẹriba.
- mf Jesu, emi ko le ṣai gbẹkẹle Ọ,
Iṣẹ Rẹ l’ aiye, kùn f’anu, ati’ ifẹ;
mp Ẹlẹṣẹ yi Ọ ka, adẹtẹ ti Ọ,---
Kò s’ẹni buruju, ti ‘Wọ kò le gbà.
- mf Jesu, mo le gbẹkẹ mi le ọrọ Rẹ,
Bi nkò tilẹ gb’ ohùn anu Rẹ ri,
‘Gbat’ Ẹmi Rẹ nkọni, o ti dùn pọ̀ to,---
di Ki nsa fi ‘baralẹ, k’ẹkọ́ l’ẹsẹ Rẹ.
- f Jesu, totọ-tòtọ, mo gbẹkẹle Ọ:
Ẹnikẹni t’o wá, ‘Wọ ki o tanù;
ff Otọ ni ‘leri Rẹ, ọ̀wọ̀n l’ẹjẹ Rẹ;
Wọnyi ni ‘gbala mi, ‘Wọ l’Ọlọrun mi. Amin.