Hymn 175: Come, ye sinners, poor and wretched

Otosi elese, e wa

  1. mf Otoṣi ẹlẹṣẹ, ẹ wa,
    Wa ni wakati anu;
    Jesu ṣetan lati gbà nyin,
    O kun f’anu at’ ifẹ:
    cr O si le ṣe, o mura tan, má foiya.

  2. mf Ẹnyin alaini, ẹ wa gba
    Ogo Ọlọrun lọfẹ,
    ‘Gbagbọ totọ, ‘ronu totọ,
    Or’ ọfẹ ti o nfà wa,
    cr Wa ‘dọ Jesu, laini owo, sa wa rà.

  3. mp Má jẹ k’ ọkàn nyin da nyin ró,
    Maṣe ro ti aiyẹ nyin;
    Gbogbo yiyẹ t’ O mbere ni,
    Ki ẹ sa mọ aini nyin:
    cr ‘Yi l’ O fun nyin; ‘tanṣan Ẹmi l’ ọkàn.

  4. mp Ẹnyin t’ẹrù npa, t’arẹ mu,
    T’ ẹ sọnu r’ẹ si ṣègbe,
    Bi ẹ duro tit’ ẹo fi, sàn
    Ẹ kì yio wà rara:
    cr F’ẹlẹṣẹ ni, On kò wá f’ olododo.

  5. mf Ọlọrun goke l’awọ́ wa,
    O nfi ẹjẹ Rẹ̀ bẹ̀bẹ̀,
    cr Gbe ara le patapata;
    Má gbẹkẹle ohun mi:
    f Jesu nikan l;o le ṣ’ẹlẹṣẹ l’ore.

  6. ff Angẹli at’ awọn mimọ
    Nkọrin ‘yin Ọdagutan;
    Gbohungbohun Orukọ Rẹ̀
    Si gba gbogbo ọrun kan:
    Halleluya! ẹlẹṣẹ le gberin na. Amin.