Hymn 174: I lay my sins on Jesus

Mo k’ ese mi le Jesu

  1. mf Mo k’ ẹṣẹ mi le Jesu,
    Ọd’ agutan mimọ;
    O rù gbogbo ẹrù mi,
    O sọ mi d’ ominira;
    Mo rù ẹbi mi tọ wa,
    K’o wẹ̀ eri mi nù,
    cr K’ẹjẹ Rẹ̀ iyebiye,
    Le sọ mi di funfun.

  2. mf Mo k’ aini mi le Jesu,
    Tirẹ̀ l’ohun gbogbo;
    O w’arùn mi gbogbo sàn,
    O r’ ẹmi mi pada;
    Mo ko ibanujẹ mi,
    Ẹrù, at’ aniyàn,
    f Le Jesu, o sì gbà mi,
    O gbà irora mi.

  3. mf Mo gb’ ọkàn mi le Jesu,
    Ọkàn arẹ mi yi;
    cr Ọw’ ọtun Rẹ̀ gbá mi mu,
    Mo simi l’aiya Rẹ̀:
    f Mo fẹ orukọ Jesu,
    Emmanuel, Kristi,
    Bi orùn didùn yika,
    Ni orukọ Rẹ̀ jẹ́.

  4. mf Mo fẹ ki nri bi Jesu,
    p T’ọkàn Rẹ̀ kun fun ‘fẹ;
    mf Mo fẹ ki nri bi Jesu,
    p Ọmọ Mimọ Baba;
    f Mo fẹ ki mba Jesu gbe,
    Larin ẹgbẹ́ mimọ,
    cr Ki nkọrin iyin titi,
    Orin t’ angẹli nkọ. Amin.