mp Jesu, nigba’ danwò, Gbadura fun mi; K’emi má bà sẹ́ Ọ, Ki nsi ṣako lọ: cr ‘Gba mba nṣiyemeji, K’o bojuwò mi; L’ẹ̀ru tab’ isaju, Ma mu mi ṣubu.
mp B’aiye ba si nfà mi, Pẹlu adùn rẹ̀; T’ ohun ‘ṣura aiye Fẹ hàn mi l’emọ́; Jọ mù Getsemane di Wa s’ iranti mi, pp Tabi irora Rẹ, L’oke Kalfari.
mp B’o ba pọn mi l’oju, Ninu ifẹ Rẹ; Dà obilim Rẹ le, Ori ẹbọ na: Ki mf’ara mi fun Ọ. Lori pẹpẹ Rẹ; B’ ara kọ̀ ago na, Igbagbọ y’o mu.
p ‘Gbà mo ba nrè boji, Sinu ekuru; cr T’ ogo ọrun si nkọ, L’eti bèbe na; mf Ngo gbẹkẹl’ otọ Rẹ, N’ ijakadi ‘ku, Oluwa, gb’ẹmi mi, f S’ iye ailopin. Amin.