- p Bi mo ti ri --- laiṣawawi,
Ṣugbọn nitori ẹjẹ Rẹ;
B’ o si ti pè mi pe ki nmà---
cr Olugbala, mo de.
- p Bi mo ti ri --- laiduro pẹ,
Mo fẹ k’ ọkàn mi mọ́ toto,
S’ọdọ Rẹ t’o le wẹ̀ mi mọ ,
cr Olugbala, mo de.
- Bi mo ti ri --- b’o tilẹ jẹ
Ijà l’ode, ija ninu;
Ẹru l’ode, ẹru ninu,---
cr Olugbala, mo de.
- p Bi mo ti ri --- òṣi, are,
cr Mo si nwa imularada;
Iwọ l’o le s’awotán mi, ----
Olugbala, mo de.
- mf Bi mo ti ri --- ‘Wọ o gbà mi,
Wọ o gbà mi t’ọwọ t’ẹsẹ;
cr ‘Tori mo gbà ‘leri Rẹ gbọ,----
Olugbala, mo de.
- p Bi mo ti ri ---- ifẹ Tirẹ,
cr L’o ṣẹtẹ̀ mi patapata;
f Mo di tirẹ, tire nikan,---
Olugbala, mo de. Amin.