- mp Bi agbọnrin ti nmi hẹlẹ,
S’ ìpa odo omi;
cr Bẹni ọkàn mi nmi si Ọ,
Iwọ Ọlọrun mi.
- mp Orungbẹ Rẹ ngbẹ ọkàn mi,
Ọlọrun alayè;
p Nigbawo ni ngo r’oju Rẹ,
Ọlọrun Ọlanla?
- p Ọkàn mi, o ṣe rẹwẹsi?
Gbẹkẹle Ọlọrun;
cr Ẹniti y’o sọ ẹkún rẹ
D’ orin ayọ̀ fun ọ.
- mp Y’o ti pẹ tó, Ọlọrun mi,
Ti ngo d’ẹni ‘gbagbe?
Tao ma ti mi sihin sọhun,
B’ ẹni kò ni ‘bugbe?
- mp Ọkàn mi, o ṣe rẹwẹsi?
cr Gbagbọ, ‘wọ o si kọ
f Orin iyin s’ Ọlọrun rẹ.
Orisun ẹmi rẹ. Amin.