- mp Sa dakẹ ọkan mi,
Oluwa rẹ wà mbẹ̀;
Ẹnit’ o ti ṣe ileri,
Yio fẹ mu u ṣẹ.
- mf On ti fà ọ lọwọ,
O mu ọ de ‘hinyi;
Y’o pa ọ mọ là ewu ja,
Tit’ opin aiye rẹ.
- Nigbat’ iwọ ti bọ
Sinu wahala ri,
Igbe rẹ na ki On ha gbọ,
T’ o si yọ ọ kuro?
- B’ ọ̀na kò tilẹ dán,
Yio mu ọ de ‘le;
f Sa ti wahala aiye tan,
O san fun gbogbo rẹ̀. Amin.