- mf L’oju alẹ, ‘gbat ‘orùn wọ̀,
Nwon gbe abirùn w’ ọdọ Rẹ:
p Oniruru ni aisàn wọn,
f Ṣugbọn nwọn f’ayọ lọ ‘le wọn.
- mf Jesu a de l’ oj’ alẹ yi,
A sunmọ, t’ awa t’ àrun wa,
cr Bi a ko tilẹ lè ri Ọ,
Ṣugbọn a mọ̀ p’ O sunmọ wa.
- mpOlugbala, wò òṣi wa;
Omi kò sàn, mì banuje,
Omi kò ni ifẹ si Ọ,
Ifẹ ẹlomi si tutu.
- Omi mọ pe, asan l’ aiye
Bẹni nwọn kò f’ aiye silẹ
Omi l’ ọrẹ́ ti ko se ‘re,
Bẹni nwọn ko fi Ọ ṣ’ọrẹ́.
- Ko s’ ọkan ninu wa t’ o pé
Gbogbo wa si ni ẹlẹṣẹ;
Awọn t’ o si nsìn Ọ totọ
Mọ ara wọn ni alaipé.
- mf Ṣugbọn Jesu Olugbala,
Ẹni bi awa n’ Iwo ‘se:
‘Wọ ti ri ‘danwo bi awa
‘Wọ si ti mọ ailera wa.
- Agbar’ ọwọ Rẹ wà sibẹ̀
Ore Rẹ si li agbara
p Gbó adura alẹ wa yi
cr Ni anu, wo gbogbo wa sàn. Amin.