- mp Apata aiyeraye,
Ṣe ibi isadi mi;
cr Jẹ ki omi on ẹjẹ
T’ o ṣàn lati iha Rẹ,
Ṣe iwosan f’ ẹ̀ṣẹ mi,
K’ o si sọ mi di mimọ́.
- mf K’ iṣe iṣẹ ọwọ mi
L’ o lè mu ofin Rẹ ṣẹ;
B’ itara mi kò l’ àrẹ́,
T’ omije mi nṣan titi;
Nwọn kò to fun ètutu,
‘Wọ nikan l’ o lè gbala.
- p Ko s’ ohun ti mo mu wá
Mo rọ̀ mọ agbelebu;
Mo wà, k’ o d’aṣọ bò mi,
Mo nwò Ọ fun iranwọ;
Mo wá sib’ orisun nì,
cr Wẹ mi, Olugbala mi.
- mp ‘Gbati ẹmi mi ba nlọ,
p T’ ikú ba p’ oju mi de,
cr Ti mba nlọ s’ aiye aimọ̀,
Ti nri Ọ n’ itẹ dajọ;
di Apata aiyeraiye,
pp Ṣe ibi isadi mi. Amin.