Hymn 168: Jesus, Lover of my soul

Jesu oluf’ okan mi

  1. mp Jesu oluf’ ọkàn mi,
    Jẹ ki nsala s’ aiya Rẹ,
    cr Sa t’irumi sunmọ mi,
    Sa ti iji nfẹ s’ oke;
    mf Pa mi mọ Olugbala,
    Tit’ iji aiye y’o pin,
    di Tọ mi lọ s’ ebute Rẹ,
    p Nikẹhin gbà ọkan mi.

  2. mf Abo mi, emi kò ni,
    Iwọ l’ ọkàn mi rọ̀ mọ;
    di Má f’ emi nikan silẹ̀,
    Gba mi, si tù mi ninu,
    cr Iwọ ni mo gbẹkẹle,
    Iwọ n’ iranlọwọ mi;
    mf Mà ṣai f’ iyẹ apa Rẹ
    D’ abob’ ori àibo mi.

  3. mf Krist ‘Wọ nikan ni mo fẹ,
    N’nu Rẹ, mo r’ohun gbogbo;
    Gb’ ẹni t’o ṣubu dide,
    W’ alaisàn, tọ́ afọju;
    Ododo l’orukọ Rẹ,
    p Alaiṣododo l’ emi,
    Mo kun fun ẹ̀ṣẹ pupọ,
    mf Iwọ kun fun ododo.

  4. cr ‘Wọ l’ ọpọ ore-ọfẹ
    Lati fi bò ẹṣẹ mi;
    Jẹ ki omi iwosan
    Wẹ inu ọkan mi mọ́;
    f Iwọ l’ orisun iyè,
    Jẹ ki mbù n’nu Rẹ l’ọfẹ;
    Ru jade n’nu ọkàn mi.
    Si iye ainipẹkun. Amin.