- Ki ṣe l’ainireti
Ni mo tọ wa;
Ki ṣe l’aini ‘gbagbọ
Ni mo kunlẹ;
Ẹṣẹ ti gori mi,
cr Eyi ṣa l’ẹ̀bẹ mi, Eyi ṣa l’ẹ̀bẹ mi,
Jesu ti ku.
- p A! ẹ̀ṣẹ mi pọju,
O pọn kọkọ!
Adálé, adálé,
Ni mo nd’ ẹṣẹ!
Ẹṣẹ aiferan Rẹ;
Ẹṣẹ aìgba Ọ gbọ; Ẹṣẹ aìgba Ọ gbọ;
Ẹṣẹ nlanla!
- mp Oluwa mo jẹwọ
Ẹṣẹ nla mi;
O mọ bi mo ti ri,
Bi mo ti wà;
p Jọ wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù !
K’ ọkàn mi mó loni, K’ ọkàn mi mó loni,
Ki ndi mimọ.
- mf Olododo ni Ọ
O ndariji;
L’ ẹsẹ̀ agbelebu
Ni mo wolẹ̀;
p Jẹ k’ ẹjẹ iwẹ̀nù,
Ẹjẹ Ọdagutan, Ẹjẹ Odagutan,
Wẹ̀ ọkan mi.
- cr ‘Gbana, alafia
Y’o d’ọkàn mi;
‘Gbana, ngo ba Ọ rìn,
Ọrẹ airi;
mf Em’ o f’ ara ti Ọ,
Jọ ma tó mi s’ọ̀na, Jọ ma to mi s’ọ̀na,
Titi aiye. Amin.