- mf Krist t’ agbelebu l’ orin wa,
Ijinlẹ t’ awa nsọ;
O j’ ẹgàn loju awọn Ju,
Werè lọwọ Griki.
- Ṣugbọn ọkàn t’ Ọlọrun kọ́
F’ ayọ̀ gba ọ̀rọ na;
Nwọn ri ọgbọn, ipa, ifẹ,
T’ o hàn n’Oluwa wọn.
- f Adùn orukọ Rẹ̀ yiyè
Mu ‘sọji s’ọkàn wọn;
Aigbagbọ l’ohun t’ o ba ni jẹ,
p Si ẹbi at’ ikú.
- Lai j’Ọlọrun t’ o or’ ọfẹ ka
Bi ọwara ojò;
Lasan l’Apọllọs funrugbin,
Paul si le gbìn lasan.