Hymn 165: To the altar of God

Si pepe Oluwa

  1. p Si pẹpẹ Oluwa,
    mo mu ‘banujẹ wá;
    ‘Wọ ki o f’ anu tẹwọgba
    Ohun alaiyẹ yi?

  2. mf Kristi Ọdagutan
    Ni igbagbọ mi nwò:
    p ‘Wọ le kọ ‘hun alaiyẹ yi?
    ‘Wọ o gba ẹbọ mi.

  3. p ‘Gbati Jesu mi kú,
    A tẹ ofin l’ ọrùn;
    Ofin kò bà mi l’ ẹru mọ
    p “Tori pe Jesu kú. Amin.