Hymn 164: Thou Who didst on Calvary bleed

’Wo t’ o ku ni Kalfari

  1. ‘Wọ t’ o ku ni Kalfari,
    ‘Wọ t’o mbẹ̀bẹ f’ẹlẹṣẹ,
    Ràn mi lọwọ nigb’ aini;
    Jesu, gbọ ‘gbe mi.

  2. Ninu ibanujẹ mi,
    At’ ọkàn aigbagbọ mi,
    Em’ olori ẹlẹṣe
    Gb’oju mi si Ọ.

  3. Ọta lode, ẹ̀ru n’nu,
    Kò s’ ire kan lọwọ mi,
    cr Iwọ l’o ngb’ ẹlẹṣẹ là,
    p Mo sa tọ̀ Ọ wá.

  4. cr Awọn miran dẹṣẹ pẹ,
    Nwọn si ri igbala gbà,
    Nwọn gbọ ohùn anu Rẹ,
    Mu mi gbọ pẹlu.

  5. Mo k’ aniyàn mi le Ọ,
    Mo si ngbadua si Ọ,
    Jesu, yọ mi n’nu ègbé,
    Gbà mi, ki mmá ku.

  6. ‘Gbati wahala ba de,
    Nigb’ agbara idanwò,
    Ati lọjọ iẹkhìn,
    Jesu, sunmọ mi. Amin.