Hymn 162: Weary of wandering from my God

O su mi lati ma sako

  1. mp O su mi lati ma ṣako,
    O to gẹ, ngo wa Ọlọrun:
    Mo tẹriba fun ọpa Rẹ;
    Fun Ọ mo ns’ọ̀fọ̀ n’nu ‘reti;
    cr Mo n’Alagbawi kan loke,
    Ọrẹ niwaju ‘tẹ ifẹ.

  2. mf A! Jesu t’o kun f’or’ọfẹ
    Ju bi mo ti kun fun ẹṣẹ,
    Lẹkan si mo tun nw’oju Rẹ,
    N’apa Rẹ, si gbá mi mọra;
    L’ọfẹ wo ‘fasẹhin mi san,
    Fẹ em’ alaigbagbọ sibẹ.

  3. mp ‘Wọ m’ọna lati pè mi bọ̀,
    Lati gb’ẹmi t’o ṣubu ró;
    A! ‘tor’anu at’otọ Rẹ,
    Dariji, má jẹ ki m’ṣẹ̀ mọ;
    cr Tun ibajẹ ọkàn mi ṣe,
    K’ o si ṣe n’ile adura.

  4. mp A! fun mi ni ọkàn rírọ̀,
    Ti y’o ma wariri f’ẹṣẹ;
    Fun mi ni ibẹru f’ẹṣẹ,
    Mu k’o ta gbongbo ninu mi;
    cr Ki nle bẹru agbara Rẹ,
    Ki nmá tun jẹ ṣẹ́ si Ọ mọ. Amin.