- mfPẹlu mi nibi ti mo nlọ,
Kọ mi l’ohun t’ emi o ṣe;
Sa gbọ arò at’ ọ̀rọ mi,
K’ o f’ ẹsẹ mi le ọ̀na Rẹ.
- Fi ọpọ ife Rẹ fun mi,
Ma ṣe alabo mi lailai;
Fi edidi Rẹ s’aiya mi,
Jẹ ki Emi Rẹ pelu mi.
- Kọ mi bi a ti gbadura,
Jẹ ki emi gba Iwọ gbọ;
Ki nkorira nkan t’ o ko fe,
K’ emi si fẹ ‘hun ti O fe. Amin.