- mp Baba má yi oju kuro,
Fun emi otoṣi;
Ti npohunrere ẹ̀ṣẹ mi
N’ iwaju itẹ Rẹ.
- ‘Lẹkun anu t’ o ṣi silẹ,
F’ akerora ẹ̀ṣẹ,
p Màṣe ti mọ mi Oluwa
Jẹ ki emi wọle.
- mp Emi kò ni pe mo njẹwọ
B’ aiye mi ti ri rí;
Gbogbo rẹ̀ l’at’ ẹhinwa, ni
‘Wọ mọ̀ dajudaju.
- mf Mo wá si ‘lekun anu Rẹ,
Nibiti anu pọ;
Mo fẹ ‘dariji ẹ̀ṣẹ mi,
K’ o mu ọkàn mi da.
- mf Emi kó ni ma tẹnumọ
Itunu ti mo nfẹ;
‘Wọ mọ̀, Baba, ki’ m to bere,
Ibukun t’ emi nwa.
- cr Anu, Oluwa, ni mo fẹ
Eyiyi l’opin na;
Oluwa, anu l’ o yẹ mi,
Jẹ ki anu Rẹ wá. Amin.