- mf Iwo Imọlẹ ọkàn mi,
Li ọdọ Rẹ oru kò si,
Ki kuku aiye má bò Ọ,
Kuro l’ oju iranṣẹ Rẹ.
- pp Nigbat’ orun alẹ didun
Ba npa ipenpeju mi de,
K’ erò mi je lati simi
Lai, l’aiya Olugbala mi.
- mf Ba mi gbe l’ orọ tit; alẹ,
Laisi Rẹ, emi kò lè wà;
p Ba mi gbe gbat’ ilẹ ba nṣú,
Laisi Rẹ, emi ko le kù.
- Bi otoṣi ọmọ Rẹ kan
Ba tapa s’ọrọ Rẹ loni,
cr Oluwa ṣiṣe ore Rẹ,
Má jẹ k’o sùn ninu ẹ̀ṣẹ.
- mf Bukun fun awọn alaisan,
Pèse fun awọn talaka;
di K’orun alawẹ̀ l’ alẹ yi,
pp Dabi orun ọmọ titun.
- cr Sure tun wa nigbat’ a ji,
K’ a to m’ ohun aiye yi ṣe,
f Titi awa o de b’ ìfe
T’ a o si de ìjọba Rẹ. Amin.