- f Oluwa, gbọ aroye mi,
Gbọ adura ikọkọ mi;
Lọdọ Rẹ nikan, Ọba mi,
L’ emi o ma wá iranwọ.
- mf L’ orọ Iwọ o gbohùn mi;
L' afẹmọjumọ ọjọ na;
Ni ọdọ Rẹ l’emi o wò,
Si Ọ l’ emi o gbadura.
- Ṣugbọn nigb’ ore-ọfẹ Rẹ
Ba mu mi de agbala Rẹ,
Ọdọ Rẹ l’ em’ o tẹju mọ.
Nibẹ ngo sìn Ọ n’ irẹlẹ.
- f Jẹ k’ awọn t’ o gbẹkẹle Ọ,
ff L’ohun rara wi ayọ̀ won:
Jẹ k’ awọn t’Iwọ pamọ yọ̀,
Awọn t’ o fẹ orukọ Rẹ.
- f Si olododo l’ Oluwa
O nà ọwọ ibukun Rẹ̀;
Ojurere Rẹ̀ l’ enia Rẹ̀
Yio si fi ṣe asa wọn. Amin.