- mf Ọlọrun, fi ọpa Rẹ,
p Bà mi li ori jẹjẹ,
Dawọ ‘binu Rẹ duro,
Ki mmá subu labẹ rẹ̀.
- p Wò ailera mi yi san,
Wo mi, mo nwá ore Rẹ;
Eyi nikan l’ẹbẹ mi,
Wo mi, nipa anu Rẹ.
- Tal’ o wà n’ isa-okú,
T’ o le sọ ti gbala Rẹ?
Oluwa, d’ọkàn mi ró,
f Fọhun, emi o si yè.
- Wo! o de! o gb’ ẹbẹ mi,
O de! ojiji kọja;
Ogo si tun yi mi ka,
Ọkàn mi, dide, k’o yin. Amin.