Hymn 157: When At Thy Footstool, Lord, I Bend

Bi mo ti kunle, Oluwa

  1. p Bi mo ti kunlẹ, Oluwa,
    Ti mo mbẹ̀ f’ anu lọdọ Rẹ,
    cr Wò t’ Ọrẹ ‘lẹṣẹ ti nku lọ,
    Si tori Rẹ̀ gb’ adura mi.

  2. p Ma ro ‘tiju at’ ẹbi mi.
    At’ aimoye abawọn mi,
    cr Rò t’ ẹjẹ ti Jesu ta ‘lẹ,
    Fun dariji on iye mi.

  3. mf Ranti bi mo ti jẹ Tirẹ,
    p Ti mo jẹ̀ ẹda ọwọ Rẹ;
    Rò b’ ọkàn mi ti fà s’ẹṣẹ,
    Bi ‘danwo si ti yi mi ka.

  4. mf A! ronu ọ̀rọ mimọ Rẹ,
    Ati gbogbo ileri Rẹ;
    Pe ‘Wọ o gbọ adua titi,
    Ogo Rẹ ni lati dasi.

  5. p A! má ró ti ‘yemeji mi,
    Ati ailo or’ ọfẹ Rẹ;
    Ro ti omije Jesu mi,
    cr Si fi ‘toye Rẹ di temi.

  6. mf Oju on eti Rẹ ko sé,
    Agbara Rẹ ko le yẹ lai;
    Jọ wo mi, ọkàn mi wuwo,
    p Da mi si, k’ O ràn mi lọwọ. Amin.