- mf Rò ipọnju mi, Oluwa,
Ran iranlọwọ Rẹ!
Ọkàn mi daku fun ‘gbala,
Iṣẹ mi ki o pin?
- Mo ri pe o dara fun mi,
p Ki Baba mi nà mi;
Iya mu mi kọ́ ofin Rẹ,
Ki mgbẹkẹ mi le Ọ.
- Mo mọ̀ pe idajọ Rẹ tọ,
Bi o tilẹ̀ muna;
Ipọnju ti mo foriti
O ti ọdọ Rẹ wá.
- mf K’ emi to m’ ọwọ ina Rẹ,
Emi a ma ṣina;
Ṣugbọn bi mo ti k’ ọrọ Rẹ,
Emi kò ṣako mọ. Amin.