- p Jesu, jọ ranti mi,
K’O si wẹ ‘ṣẹ mi nù;
cr Gba mi lọw’ ẹṣẹ ‘binibi,
Si wẹ ọkàn mi mọ.
- p Jesu, jọ ranti mi,
Em’ ẹni ‘nilara;
cr Ki m ṣe ‘ranṣẹ t’o n’ifẹ Re,
Ki m’tọ́ ‘simi Rẹ wò.
- mf Jesu, jọ ranti mi,
Ma’ jẹ ki nṣako lọ;
N’nu ‘damu on okùn aiye,
cr F’ ọ̀na ọrun hàn mi.
- p Jesu, jọ ranti mi,
Gba gbogbo rẹ̀ kọja,
cr Ki nle r’ogo ainipẹkun,
Ki nsi le ba Ọ yọ̀,
- mf Jesu, jo ranti mi,
cr Ki nle kọrin loke,
f Si Baba, Ẹmi at’ Iwọ,
Orin ‘yin at’ ifẹ. Amin.