- mf A f’ ayọ̀ ro ore-ọfẹ
T’ Alufa giga wa,
Ọkàn Rẹ̀ kún fun iyọnú,
Inu Rẹ̀ nyọ́ fun ‘fẹ.
- Tinutinu l’ o ndaro wa,
p O mọ̀ ailera wa;
O mọ̀ bi idanwo ti ri,
Nitori o ti rì.
- On papa l’ọjọ aiye Rẹ̀,
p O sọkun kikoro;
O mba olukukulu pín
Ninu iya ti njẹ.
- pp Jẹ ki a f’ igbagbọ ‘rẹlẹ̀
W’ anu at’ ipa Rẹ̀;
Awa o si ri igbala,
L’ akoko iyọnu. Amin.