- mf Kò tọ k’ awọn mimọ́ bèru,
Ki nwọn sọ ‘reti nu:
‘Gba nwọn kò reti ranwọ Rẹ̀,
Olugbala y’o de.
- Nigbati Abram mu ọbọ,
Ọlọrun ni, “Duro”;
Agbo ti o wà lọhun ni,
Y’o dipo ọmọ na”.
- p ‘Gba Jona rì sinu omi,
Ko rò lati yọ mọ;
Ṣugbọn Ọlọrun rán ẹja,
T’ o gbe lọ s’ ebute.
- B’ iru ipa at’ ifẹ yi
Ti pọ l’ ọ̀rọ Rẹ̀ to!
Emi ba ma k’ aniyan mi,
Le Oluwa lọwọ!
- f Ẹ duro de iranwọ Rẹ̀,
B’ o tilẹ̀ pẹ, Duro,
B’ ileri na tilẹ̀ falẹ̀,
Ṣugbọn kò le pẹ de. Amn.