- p Alaimọ́ ni emi,
Ọlọrun Oluwa!
Emi ha gbọdọ sunmọ Ọ,
T’ emi t’ ẹrù ẹ̀ṣẹ?
- Ẹrù ẹ̀ṣẹ yi npa
Ọkàn buburu mi;
Yio ha si ti buru to,
L’ oju Rẹ mimọ nì!
- p Emi o ha si kú,
Ni alaireti?
Mo r’ ayọ̀ ninu ikú Rẹ,
Fun otoọi b’ emi.
- Ẹjẹ nì ti o ta,
T’ iṣe or’ọfẹ Re;
Lè w’ ẹlẹṣẹ t’ o buruju,
Le m’ ọkàn lile rọ̀.
- pp Mo wolẹ l’ ẹsẹ Rẹ,
Jọ k’ o dariji mi;
Nihin l’ emi o wa, titi
‘Wọ o wipe, “Dide.” Amin.