- f Jesu mi, mu mi gb’ ohùn Rẹ,
S’ọ̀rọ alafia;
Gbogbo ipa mi
Lati yin ore Rẹ̀.
- p Fi iyọnu pè mi l’ ọmọ,
K’o si dariji mi;
Ohùn na yio dunmọ mi,
B’ iro orin ọrun.
- f Ibikibi t’ o tọ̀ mi si,
L’emi o f’ ayọ lọ;
Tayọtayọ l’emi o si
Dapọ m’ awọn oku.
- f ‘Gba ẹ̀ru ẹbi ba kọja,
Ẹru mi kò si mọ;
Ọwọ t’ o fun ‘dariji ka,
Y’o pín ade iyè. Amin.