Hymn 150: When they turned against mount Zion

Nigba nwon kehin si Sion

  1. mf Nigbà nwọn kẹhin si Sion,
    A! ọpọ n’iye wọn;
    Mo ṣeb’ Olugbala wi pe,
    p ‘Wọ fẹ kọ̀ mi pẹlu?

  2. T’ emi t’ ọkàn b’ iru eyi,
    Afi b’ O dì mi mu;
    Nkò le ṣe ki nma fà sẹhin,
    K’ emi si dabi wọn.

  3. f Mo mọ̀, Iwọ l’o l’ agbara
    Lati gbà otoṣi;
    Ọdọ tani emi o lọ,
    Bi mo k’ ẹhin si Ọ?

  4. f O da mi loju papa pe
    Iwọ ni Kristi na!
    Ẹni t’ o ni ẹmi iye,
    Nipa ti ẹjẹ Rẹ̀.

  5. mf Ohùn Rẹ f’ isimi fun mi,
    O si l’ ẹ̀ru mi lọ;
    Ifẹ Rẹ l’ o lè mu mi yọ̀
    O si ti f’ ọkàn mi

  6. Bi ‘bere yi ti dùn mi to,
    p “Pe emi o lọ bi?”
    f Oluwa, ni ‘gbẹkẹle Rẹ,
    Mo dahun pe “Bẹkọ.” Amin.