- mp Jìna s’ìle ọrun,
S’okan aiya Baba,
Ẹmi ‘bukun, wá, mo ndaku,
Mu mi rè ‘bi ‘simi.
- Mo fi duru mi kọ́
S’ori igi willo;
Ngo ṣe kọrin ayo, gbati
‘Wọ koi t’ahọn mi ṣe?
- Ẹmi mi lọ sile,
A! mbá le fò de ‘bẹ:
Ayun rẹ nyun mi, ‘wọ Sion,
Gbà mo ba ranti rẹ.
- cr Sọdọ Rẹ mo nt’ọna,
To kun fun iṣoro;
Gbawo ni ngo kọj’aginju,
De ‘le awọn mimọ?
- mf Sunmọ mi, Ọlọrun,
‘Wọ ni mo gbẹkẹle;
Sin mi là aginju aiye,
Ki m’ de ‘le nikẹhin. Amin.