- f Baba wa ọrun npè,
Krist npè wa sọdọ Rẹ̀;
Ọrẹ wa pẹlu wọn o dùn,
‘Dapọ wa y’o ṣ’ ọwọ́n.
- mp Ọlọrun nkanu mi;
O dar’ ẹ̀ṣẹ mi ji,
Olodumare ṣ’ ọkàn mi,
O f’ọgbọn tọ ‘pa mi.
- Ẹbun Rẹ̀ ti pọ to!
O l’ ọpọ iṣura,
T’a t’ọwọ Olugbala pin,
Ti a f’ẹjẹ Rẹ̀ rà!
- f Jesu Ori ‘ye mi,
Mo fi bukún fun Ọ;
Alagbawi lọdọ Baba,
Aṣaju lọdọ Rẹ̀.
- Ọkàn at’ ifẹ mi,
Ẹ duro jẹ nihin;
Titi ‘dapọ yio fi kún
L’ oke ọrun l’ọhun. Amin.