mf Jesu, agbara mi, Iwọ l’aniyan mi; Emi fi igbagbọ wòke, Iwọ l’o ngb’ adura. Jẹ ki nduro dè Ọ, Ki nle ṣe ifẹ Rẹ, Ki Iwọ Olodumare, K’o sọ mi di ọtún.
p Fun mi l’ ọkàn ‘rẹlẹ, Ti ‘ma sẹ́ ara rẹ̀; Ti ntẹmọlẹ, ti kó nani Ikẹkùn Satani; Ọkàn t’ ara rẹ̀ mọ̀ p Irora at’ iṣẹ́; T’o nfi suru at’ igboiya Ru Agbelebu rẹ̀.
mf Fun mi l’ ẹ̀ru ọrun, Oju t’o mu hánhán, T’ y’o wò Ọ n’gb’, ẹṣẹ sunmọlẹ, K’o ri b’Eu t nsá. Fun mi ni ẹmi ni, T’o ti pèse tẹlẹ; f Ẹmi t’ nduro gangan lai, T’o nf’ adura ṣọnà.
mf Mo gbẹkẹl’ ọ̀rọ Rẹ, ‘Wọ l’o leri fun mi; Iranwọ at’ igbala mi Y’o t’ ọdọ Rẹ wá sẹ. Sa jẹ ki nle duro, K’ ireti mi má yẹ̀, Tit’ Iwọ o fi m’ ọkàn mi Wọ ‘nu isimi Rẹ. Amin.