- mp Ẹlẹṣẹ; --- mo nfẹ ‘bukun;
Onde; --- mo fẹ d’ omnira;
Alarẹ̀; --- mo nfẹ ‘simi;
p “Ọlọrun ṣanu fun mi,”
- mp Ire kan emi kò ni,
Ẹṣẹ ṣa l’o yi mi ka,
Eyi nikan l’ẹ̀bẹ mi.
p “Ọlọrun ṣanu fun mi,”
- mp Irobinujẹ ọkàn!
Nkò gbọdọ gboju s’oke;
Iwọ sa mo ẹdun mi;
p “Ọlọrun ṣanu fun mi,”
- cr Ọkàn ẹ̀ṣẹ mi yi nfẹ
Sá wà simi laìye Rẹ:
Lat’ oni, mo di Tirẹ;
p “Ọlọrun ṣanu fun mi,”
- mf Ẹnikan mbẹ lor’ itẹ;
Ninu Rẹ̀ nikanṣoṣo
f N’ireti at’ ẹbẹ mi:
p “Ọlọrun ṣanu fun mi,”
- On o gbà ọ̀ran mi rò,
On ni Alagbawi mi;
Nitori Tirẹ̀ nikan,
p “Ọlọrun ṣanu fun mi” Amin.