Hymn 144: Approach, my soul, the mercy seat

Okan mi, sunmo ’te anu

  1. mf Ọkàn mi, sunmọ ‘tẹ anu,
    Nibi Jesu ngb’ ẹbẹ,
    F’ irẹlẹ wolẹ l’ẹsẹ Rẹ̀,
    ‘Wọ ko lè gbe nibe.

  2. mp Ileri Rẹ, ni ẹbẹ mi,
    Ei ni mo mu wá;
    Iwọ npè ọkàn t’ẹrù npa,
    Bi emi, Oluwa.

  3. p Ẹrù ẹ̀ṣẹ wọ̀ mi l’ọrùn,
    Eṣu nṣẹ mi n’ iṣẹ;
    Ogun l’ ode, ẹ̀ru ninu,
    Mo wá isimi mi.

  4. mf Ṣe Apata at’ Asa mi.
    Ki nfi Ọ ṣe àbo;
    cr Ki ndoju ti Olufisùn,
    Ki nsọ pe Kristi kú.

  5. mf Ifẹ iyanu! Iwọ kú,
    p Iwọ rù itiju;
    cr Ki ẹlẹṣẹ b’ iru emi,
    Lè bẹ̀ l’ orukọ Rẹ. Amin.