- mp Oluwa, má moju kuro
L’ọdọ emi t’ o nyilẹ;
Ti nsọkun ẹ̀ṣẹ aiye mi,
N’itẹ anu ifẹ Rẹ.
- mp Má ba mi lọ sinu ‘dajọ,
Bi ẹ̀ṣẹ mi ti pọ to;
Nitori mo mọ̀ daju pe,
Emi kò wà lailẹbi.
- mp Iwọ mọ̀, ki nto jẹwọ rẹ̀,
Bi mo ti nṣe laiye mi;
At’ iwa isisiyi mi,
Gbogbo rẹ̀ l’o kiyesi.
- mf Emi kò ni f’ atunwi ṣe,
Ohun ti mo fẹ tọrọ
Ni iwọ mọ̀ ki nto bere,
Anu ni lọpọlọpọ.
- pp Anu Oluwa ni mo fẹ;
Eyi l’opin gbogbo rẹ;
Tori an ni mo ntọrọ,
Jẹki nri anu gbà. Amin.