- p Jesu, l’ọjọ anu yi,
Ki akoko to kọja,
A wolẹ ni ekun wa.
- p Oluwa, m’ẹkùn gbọ̀n wa,
Fi ẹ̀ru kùn aiya wa,
Ki ọjọ iku to de.
- Tú Ẹmi Rẹ s’ọkàn wa,
L’ẹnu-ọna Rẹ l’a nke:
K’ilẹkùn anu to sé.
- pp ‘Tori ‘waiya-ija Rẹ,
‘Tori ogun-ẹ̀jẹ Rẹ,
‘Tori iku Rẹ fun wa.
- p ‘Tor’ ẹkun kikoro Rẹ,
Lori Jerusalẹmu,
Mà jẹ k’a gàn ifẹ Rẹ.
- Iwọ Onidajọ wa,
‘Gbat’ oju wa ba ri Ọ,
Fun wa n’ipò lọdọ Rẹ.
- mf Ifẹ Rẹ l’a simi le,
N’ile wa l’oke lao mò
B’ifẹ na ti tobi to. Amin.