Hymn 140: Jesus shall reign where e'er the sun

Jesu y’o joba ni gbogbo

  1. f Jesu y’o jọba ni gbogbo
    Ibit’ a ba le ri orùn;
    ‘Jọba Rẹ̀ y’o tan kakiri,
    ‘Jọba Rẹ̀ ki o nipekun.

  2. mf On l’ao ma gbadura si,
    Awọn ọba y’o pe l’Ọba;
    Orukọ Rẹ̀ b’orùn didun,
    Y’o ba ẹbọ orọ̀ goke.

  3. Gbogbo oniruru ede,
    Y’o fi ‘fẹ Rẹ̀ kọrin didun:
    p Awọn ọmọde o jẹwọ
    Pe, ‘bukun wọn t’ọdọ Rẹ̀ wá.

  4. f ‘Bukun pọ̀ nibit’ On jọba:
    A tú awọn onde silẹ;
    Awọn alarẹ̀ ri ‘simi;
    Alaini si ri ‘bukun gbà.

  5. ff Ki gbogbo ẹda k’o dide,
    Ki nwọn f’ọla fun Ọba wa;
    K’Angẹl tun wà t’awọn t’orin,
    Ki gbogb’aiye jumọ gberin. Amin.