- f Ifẹ Rẹ da wa si loni,
L’ arẹ̀, a si dubulẹ;
Ma ṣọ wa ni ‘dakẹ oru,
K’ ọta má yọ wa lẹnu:
Jesu, ṣe olutoju wa,
Iwọ l’o dun gbẹkẹ̀le.
- Ero at’ alejo l’aiye,
A ngb’ arin awọn ọta!
Yọ wa, at’ ile wa l’ewu,
L’apa Rẹ ni k’a sùn si;
p N’ ijọ iyọnu aiye pin,
Ka le simi lọdọ Rẹ. Amin.