Wi jade larin keferi p’Oluwa l’Ọba, Wi jade ! Wi jade ! Wi jade f’orilẹ-ee, mu ki nwọn kọrin, Wi jade! Wi jade ! cr Wi jade tiiyìntiyìn pe, On o ma pọ̀ si, Pe, Ọba nla Ologo l’ Ọba alafia; ff Wi jade tayọ̀tayọ̀, bi ìji tile nja, Pe, O joko lor’ iṣàn omi, Ọba wa titi lai.
p Wi jade larin keferi pe, Jesu njọba, Wi jade! Wi jade ! Wi jade f’orilẹ-ede, mu k’ide wọn ja, Wi jade! Wi jade ! Wi jade fun awọn ti nsọokun, pe Jesu yè: Wi jade f’alarẹ pe, O nfun ni nisimi; Wi jade f’ẹlẹṣẹ pe, O wá lati gbàla; Wi jade fun awọn ti nkú pe, O ti ṣẹgun ikun.
f Wi jade larin keferi, Krist njọba loke, Wi jade! Wi jade ! Wi jade fun keferi, Ifẹ n’ ijọba Rẹ̀, Wi jade! Wi jade ! cr Wi jade lọnà opópo, l’ abuja ọ̀na. Jẹ k’o dùn jakejado ni gbogbo agbaiye: ff B’i ró omi pupọ ni k’ iho ayọ̀ wa jẹ, Titi gbohun-gbohun y’o fi gbe iró na de ‘kangun aiye. Amin.