- mf Krist’, ki ‘jọba Rẹ de,
Ki aṣẹ Rẹ bẹrẹ;
F’ ọpa-irin Rẹ fọ
Gbogbo ipá ẹṣẹ.
- p Ijọba ifẹ dà,
Ati t’alafia?
Gbawo ni irira
Yio tan bi t’ọrun?
- Akoko na ha dà
T’ọtẹ yio pari,
Ikà at’ irẹjẹ,
Pẹlu ifẹkufẹ?
- mf Oluwa jọ, dide,
Wá n’nu agbara Rẹ;
Fi ayọ fun awa
Ti o nṣafẹri Rẹ.
- p Ẹda ngàn okọ Rẹ,
Kokò njẹ agbo Rẹ;
Iwa ‘tiju pupọ̀
Nfihàn pe ‘fẹ tutu.
- Okùn bolẹ sibẹ̀,
Ni ilẹ keferi:
cr Dide ‘Rawọ orọ̀
ff Dide, maṣe wọ̀ mọ́. Amin