- mf Gbọ iró ẹfufu, lat’ ọna jijin;
cr O nsọrọ jakadi ti ogun mimọ;
f Ọlọrun mbẹ fun wa, O ti sọrọ Rẹ̀,
O si nṣọ́ gbogbo nyin, “Ojiṣẹ ọrun.”
- ff Lọ! ‘wọ Ihinrere, ma ṣẹgun titi
Okunkun ndimọlẹ , ni gbogbo aiye;
Oṣa nwolẹ fun Ọ, ile wọn si nwó,
Gbogb’ ẹda bù jẹwọ pe, ‘Wọ l’ Oluwa.
- mf Olugbala mimọ́ ti njọba loke,
K’ awọn ọm’ ogun Rẹ ma ri Ọ titi;
cr Jẹ k’ ọrọ Rẹ ma tàn lat’ ilẹ de ‘lẹ,
ff Ki gbogbo agbaiye tẹriba fun Ọ. Amin.